Gbajúgbajà akọrin Régè Majek Fashek, jáde láyé
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwáyé è kú ò sí, aláhéré á kú, iná ó dilẹ̀ lẹ́yìn asunsujẹ.
Ìjọ a kú làá dère, èèyàn ò sunwọ̀n láàyè,o ọkùnrin lọ, àjànàkú sùn bí òkè.
Gbajúgbajà akọrin Régè ni, Majẹkodunmi Fasheke tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí ‘Majek Fashek’ ti jáde láyé. Ìròyìn tó ń tẹ̀ wá lọ́wọ́ jẹ́ kó di mímọ̀ pé àṣálẹ́ ọjọ́ Ajé ló dágbére pé ó dìgbòóṣe.
Ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta ni ìlúmọ̀ọ́ká òùnkọrin Majek Fashek kí ó tó dágbére fáyé.
Iléèwòsàn kan l’órílẹ̀èdè Gẹ̀ẹ́ṣì ni ìròyìn sọ pé ó dákẹ́ sí.
Ní ìlú Benin city ni wọ́n bí Majek Fashek sí. Ọmọ Ilesha ni bàbá rẹ̀ tí ìyá rẹ̀ sì wá láti Edo.


