News

Ó jọ pé Sẹ́nétọ̀ Báyọ̀ Oṣìnọ́wọ̀ ríran ṣaájú ọlọ́jọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní kò sí ikú tí yóó pa àgbà tí kò ní ṣe é lójú fìrí.

 Àìpẹ́ yìí nikú pajú gbajúgbajà olóṣèlú ọmọ Ijẹbu ode tó ń ṣojú ẹkùn ìlà oòrùn ìlú Èkó nílé Aṣòfin àgbà, Sẹ́nétọ̀ Bayọ Oṣinọwọ dé.

Ṣùgbọ́n Ìròyìn ibẹ̀ lásìkò yìí ni fídíò kan tó lu s’órí ayélujára, ọ̀rọ̀ tí Sẹ́nétọ̀ Osinowo sọ nínú rẹ̀ èyí tó dà bí ẹni pé ó ti rí ìran ikú rẹ̀ ni.

Níbi ìjókòó ilé Aṣòfin àgbà, níbi tí wọ́n ti gbé ìjókòó kan kalẹ̀ láti fi dárò èèkàn Orílẹ̀ yìí kan tó jáde láyé ló ti ṣẹlẹ̀

Gbogbo àwọn Aṣòfin àgbà ni wọ́n sọ̀rọ̀ ní ṣíṣẹ̀ n tẹ̀lé lórí olóògbé náà láìyọ Pepperito náà sílẹ̀.

Nígbà tó kan Sẹ́nétọ̀ Oṣinọwọ láti sọ̀rọ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tó jáde lẹ́nu ‘Pepperito’ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣe máa ń pè é dàbí bíìgbà tó ti ríran ríkú ara rẹ̀ ni

Se ló wá jọ pe ó wá ń fi ọgbọ́n sọ fáwọn èèyàn irúfẹ́ nǹkan tó fẹ́ bí òun pẹ̀lú bá rèwàlẹ̀ àṣà.

Lẹ́yìn tó dárúkọ ara rẹ̀ nígbà to dìde, ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ tó jáde lẹ́nu Bayọ Oṣinọwọ ni pé,:

‘ Òní kìí ṣe ọjọ́ ẹkún gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn kan ṣe ń sọ, bíkòṣe ọjọ́ ọpẹ́ nítorí Ọlọ́run kò bá ẹnikẹ́ni dá májẹ̀mu lórí àkókò tí yóó jáde láyé nígbà tó dá kóówá.

Ọlọ́run dá wa ni láìgbọ́ àròyé ẹnikẹ́ni, yóó sì mú kóówá lọ nígbà tó bá wùú.”

 Ọ̀pọ̀ tó ti wo fídíò náà ni wọ́n ti ní ó súnmọ́ pé ara sọ olóògbé náà, ni ó fi sọ ọ̀rọ̀ náà láì mọ̀ pé òun pẹ̀lú yóó di ará ilẹ̀ láìpẹ́ jọjọ.

Sẹ́nétọ̀ Osinọwọ tó ní àkókò tó fún olúkúlùkù ó máa gbaradì fún ọjọ́ àfiyèsí ni: ‘ ọ̀pọ̀ la bí tí kò dúró ṣe ọdún kan lórí òkè erùpẹ̀,

Mélò ó la fẹ́ kà nínú oore Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ ni kò rí ọdún kẹwàá lókè erùpẹ̀. Ikú ò dọ́jọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò doṣù, gbogbo wa la dágbádá ikú’

Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ karùndínlógún ni Sẹ́nétọ̀ Adébáyọ̀ Oṣìnọ́wọ̀ jáde láyé lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *