Ìwọ́de àwọn ọ̀dọ́, Buhari pé Lawan, Gbàjàbíàmílà sí ìpàdé májẹ̀ẹ́óbàjẹ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní àgbà tí kò bá kẹhùn sọ̀rọ̀, ó ṣeéṣe kó kẹtan sáré.
Ó jọ pé iná tí jó d’órí kókó báyìí, bí Ààrẹ Muhammadu Buhari tí ń bá àwọn aṣíwájú Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ jíròrò níbi ìpàdé kan lórí ipò tí Nàìjíríà wà báyìí.
Gẹ́gẹ́ bá a ti gbọ́, àfojúsùn ìpàdé ọ̀sán ọjọ́ Ìsinmi náà ni láti wá nǹkan ṣe sáwọn ẹ̀dùn ọkàn táwọn ọ̀dọ́ tó ń sèwọ́de gbé síwájú ìjọba, èyí tó dá lórí ọ̀nà láti dẹ́kun ìwà kọ̀tọ́ àwọn ọlọ́pàá.
Ààrẹ Ilé aṣòfin àgbà, Sẹ́nétọ̀ Ahmad Lawan pẹ̀lú olórí Ilé aṣòfin-ṣojú, Fẹ́mi Gbàjàbíàmílà sì lo ń bá Ààrẹ se ìpàdé náà.
Amúgbálẹ́gbẹ̀ fún Ààrẹ Buhari lórí ọ̀rọ̀ ìbánisọ̀rọ̀ orí ayélujára, Bashir Ahmad ló fi èyí síta lójú òpó Twitter rẹ̀, @BashirAhmad.
Lẹ́yìn ìpàdé nàá, Ààrẹ ilé aṣòfin àpapọ̀, Sẹ́nétọ̀ Ahmad Lawan ṣàlàyé fún àwọn akọ̀ròyìn pé, Ìjọba àpapọ̀ ti tẹ́wọ́ gba gbogbo ẹ̀hónú àwọn ọ̀dọ́ tó ń wọ́de náà.
Ó fikún-un pé àsìkò tó fún wọn láti dẹ́kun ìwọ́de nàá, kí wọ́n lè fún Ìjọba l’áǹfàní àti ààyè láti mójútó àwọn ẹ̀hónú tí wọ́n gbé kalẹ̀.


