Covid-19 nípìnlẹ̀ Ọ̀yọ́ rárí wọ Ògbómọ̀ṣọ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìtànkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Covid-19 ti tàn ràn mọọ bíi iná pápá kọja Ibadan, wọ ìlú Ògbómọ̀ṣọ́.
Gómìnà Ṣèyí Mákindé nínú ìkéde kan tó fi síta lójú òpó abẹ́yefò rẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì sọ pé, méjì lára àwọn ènìyàn mẹ́jọ tó ṣẹṣẹ ní àrùn náà, ló wá láti ìlú Ògbómọ̀ṣọ́,awọn mẹ́fà yókù jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Togo
Gómìnà ṣàfikún ẹ̀ pé èsì àyẹ̀wò méjì míràn tó jáde ní alẹ́ ọjọ́ Ẹtì fihàn pé dókítà kan níléèwòsàn UCH n’Ìbàdàn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ìlú Kano, tí ẹnìkejì sí jẹ́ òṣìṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS.
Lọ́wọ́lọ́wọ́, ènìyàn ogún ló ń gba ìtọ́jú fún àrùn apinni léèmí Covid-19 nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́.


