Ibo Ipinle Ondo: Bí àwọn alátìlẹ́yìn ẹgbẹ́ oselu se kolu araa won
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọ̀rọ̀ tí di ara ò rọkùn, ara ò rọ adìẹ ní ìpínlẹ̀ Òǹdó látàrí ìdìbò ìpínlẹ̀ náà bí àwọn alátìlẹyìn igun ẹgbẹ́ òṣèlú méjéèjì tó hànde APC àti PDP ṣe n jìjàdù àti jáwé olúborí ní ìpínlẹ̀ náà.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbọ́ pé ọ̀kankan farapa nínú àwọn olùdíje ọ̀hún, síbẹ̀ àwọn alátìlẹyìn wọn àti àwọn eesin ò kọkú kò jẹ́ kí omi ìlú Òǹdó àti agbègbè e rẹ̀ ó tòrò fún ará ìlú lásìkò yìí. Ọ̀kan lára rẹ̀ ni tí ọkùnrin kan tí kò tíì sí àrídájú orúkọ rẹ̀, tí ìròyìn sọ pé wọn pa níbi ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn alátìlẹyìn Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, Rótìmí Akérédolú àti àwọn ti olùdíje ẹgbẹ́ alátakò ní Òǹdó ìyẹn PDP, Èyítáyọ̀ Jẹ́gẹ́dẹ́.
Ìforígbárí náà wáyé ní agbègbè Obanla nílùú Akure, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn sì farapa yàtọ̀ fún èèyàn kan tí ó forí lùgbàdi ikú.
Èèyàn kan tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣojú rẹ̀ ní fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí ni ìgbòkègbodò àti kárakára ní agbègbè náà fi dúró wápe, torí ìgboro tó dàrú .
Agbọ́n ń sẹ́, ìkaǹdù n sẹ́, ojú olóko rè é kùǹdùkundu yìí.
Àti ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti PDP ló ń di ẹ̀bi ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ru ara wọn lórí.
Láìpẹ́ yìí ni èèyàn márùn farapa lásìkò tí ẹgbẹ́ méjéèjì yìí kan náà dojú ìbọn kọ ara wọn ní ìlú Oba-Akoko tí àwọn alátìlẹyìn ẹgbẹ́ méjéèjì farapa yánayàna tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ sì bàjẹ́
Ẹ dúró ná, taa gan an làwọn asaájú wọ̀nyí fẹ́ ṣèlú lé lórí bí wọ́n bá fi ẹ̀mí àwọn alátìlẹyìn wọn sòfò tán.



