Gómìnà Akérédolú la Jẹgẹdẹ mọ́lẹ̀ wọlé sáà kejì
Fẹ́mi Akínṣọlá
Bí èèyàn méjì bá ń tayò, kò sí àní àníàní, ẹnìkan náà ní yóó gbégbá orókè
Ààrẹ orílẹ̀-èdè tí gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ yóó sì máa dunnú pẹ̀lú ẹ̀. Èyí náà ló bí bí Ààrẹ Orílẹ̀ yìí ,Muhammed Buhari ti ń kí Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, Oluwarotimi Akérédolú kú oríire pẹ̀lú bí ó ṣe jàjàborí nínú ìdìbò sípò Gómìnà tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Òǹdó.
Ààrẹ Buhari fi èyí léde gba ọwọ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì nínú ètò ìròyìn ìgbàlódé, Bahir Ahmad, eléyìí tó fi sí ojú òpó abẹ́yefò Twitter.
Ó ní ” Akérédolú kú orííre ìyànsípò gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà fún ọdún mẹ́rin míràn láti tukọ̀ ìpínlẹ̀ Ondo”.
Akérédolú ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC la Jẹ́gẹ́dẹ́ mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìbò 29,2830, tí Jẹ́gẹ́dẹ́ ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sì ní ìbò 195,791.


