NewsPhoto Speak

Ṣèyí Mákindé ń ṣèdárò ìyá rẹ̀ tó fayé sílẹ̀

 

Fẹ́mi Akínṣọlá

 “`Àwáyé è kú kò sí, bí kóówá bá tí ń dé ibùdó rẹ̀ náà ni yóó máa kóní bodè kúulé . Ní báyìí, iyá tó ṣe ọlọ́kọ̀ tó wa Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ wá sáyé, Arábìnrin Abigail Ọmọjọlágbé Mákindé ti fayé sílẹ̀ pó dìgbà kan o.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Gómìnà Mákindé fúnrarẹ̀ kò tíì fi ọ̀rọ̀ síta, Olóyè Muyiwa Mákindé tó gbẹnu ẹbí ṣọ̀rọ̀ sọ pé ìyá àwọn Màmá Abigail Mákindé dákẹ́ nílé rẹ̀ 7B, Bayo Oyeleke Street, Ikolaba, Ibadan.ní òwúrọ̀ ọjọ́bọ, ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gún oṣù Kẹwàá ọdún 2020, láì fí àìsàn fu àwọn lára. 

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí ni wọ́n ṣe ayẹyẹ ọgọ́rin ọdún tí màmá náà pé lórílẹ̀ ayé.

 Olóye Muyiwa lórúkọ ẹbí ká ìpapòdà màmá sí ti ọlọ́jọ́ tí ó níí ṣe pẹ̀lú ogbó. Ó ní màmá wa lọ sinmi ni.

Ṣaájú àsìkò yìí Gómìnà Mákindé ti ṣàpèjúwe ìyá rẹ yìí gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí í wí bẹ́ẹ̀ tí wọ́n bá a bẹ́ẹ̀. Ó ní òun fi irú ìwà yìí jọ ìyá tó bí òun lọ́mọ.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ ni Gómìnà Ṣèyí Mákindé sọ níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí tí ìyá rẹ ṣe gbẹ̀yìn èyí tó fihàn pé ó mọ rírì ìyá yìí, kò sì kó iyán rẹ̀ kéré.

.“`

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *