Ọ̀rọ̀ Obaseki l’Ẹdo, ti d’adìẹ bà lókùn láàrin ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti PDP
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọ̀rọ̀ Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo tó ń jìjàdù pé kí ẹgbẹ́ òṣèlú APC fa òun kalẹ̀ fún sáà kejì, ṣùgbọ́n tí ojú ẹ̀kọ ò fẹ́ ṣe mímu fún tí ń mú fíágan fíàgan lọ́wọ́ , bí gómìnà ọ̀hún Obaseki ṣe fẹ sọra rẹ̀ di bàbá Ìjẹ̀bú láàrin àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú méjì tó lóókọ n’ílùú náà.
Ìtẹ̀síwájú ìròyìn náà ló bí bí Gómìnà tó ń darí ìpínlẹ̀ Edo lọ́wọ́, Godwin Obaseki ṣe fi ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye lórí yíyọ tí wọ́n yọ ọwọ́ rẹ̀ kúrò láwo ìdíje fún ipò gómìnà lábẹ́ àṣìá ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Edo.
Godwin Obaseki ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lẹ́yìn ìpàdé rẹ̀ pẹ̀lú Ààrẹ Muhammadu Buhari ní ìlú Àbújá ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun.
Ó ti tó ọjọ́ mẹ́ta báyìí tí wàhálà ti bẹ́ sílẹ̀ láàrin Gómìnà Obaseki àti Alága àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Adams Oshiomhole.
Àtubọtán ìtàpórógan láàrin àwọn méjéèjì yìí gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ onwoye ọ̀rọ̀ tó jẹmọ́ òṣèlú ni bí ìgbìmọ̀ àyẹ̀wò fún àwọn olùdíje ìdìbò abẹ́lé láti yan ọmọ oyè tí yóó dúró bíi olùdíje fún ipò Gómìnà lábẹ́ àṣìá ẹgbẹ́ òṣèlú APC fi pàṣẹ pé kò ní leè kópa nítorí ohun tí wọ́n pè ní àìdọ́gba lórí àwọn ìwé ẹ̀rí rẹ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì Ìbàdàn ti bọ́ síta láti kéde pé akẹ́kọ́ọ̀jáde ilé ẹ̀kọ́ náà ni, síbẹ̀, ìgbìmọ̀ kòtẹ́milọ́rùn ti ẹgbẹ oṣelu APC gbé kalẹ̀ lórí eto àyẹ̀wò náà pẹ̀lú fọwọ́ sí ìgbésẹ̀ ìgbìmọ̀ àyẹ̀wò náà.
Níbá yìí, ìbéèrè tó wà lẹ́nu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn Orílẹ̀ yìí lásìkò yìí ni pé níbo ló kàn fún Gómìnà obaseki àbí, ṣé ó ti gbà fún Ọlọ́run náà nìyẹn.
Àmọ́ ṣá gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣe mọ̀ nípa àwọn olóṣèlú Nàìjíríà, kò ṣeéṣe kó gbà f’Ọ́lọ́run bẹ́ẹ̀.
Ohun tí ọ̀pọ̀ ń wòye rẹ̀ lọ́wọ́ báyìí ni pé bóyá yóó kó ẹrù òṣèlú rẹ̀ lọ bá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP pẹ̀lú bí ó ti ṣe ń rin ìrìnàjò káàkiri ọ̀dọ̀ àwọn Gómìnà ìpínlẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP bíi Wike ti Rivers àti Udom ti ìpínlẹ̀ Akwa Ibom.


